Saturday, December 6, 2014

ALAKISA NJO L'ORU, B'OPE TITI ILE A MO LOLA


Yoruba bo, won ni agba kin wa l'oja, ki ori omo titun wo. Sugbon owe yi nso nipa awon omoluabi, awon omo oko, ki n se ori omo ale.

Ni enu ojo meta yi, awon agba meji ni orile ede wa, mu owe yi ni ikankandun, won si ke igbe sita gbangba pe oro ilu yi ko dan maran, ki awon ti agbara wa ni owo won tete se atunse.
Sugbon, kaka ki won gba imoran awon agba, ki won o se atunse, nise ni won da awon aja won sita ki won ma gbo, ki won si ma ke ohuohu mo gbogbo eni to nfi ibi ti pata oba ti ya.
Sugbon ti awon eranko omo alainiran ba da ilu ru, sebi awon omo anibiniran a rin jina, ki awon omo atohunriwa, ti won o ni agba nile, ati awon ti won nfi ipa ji awon obi won, ki won o ma fi epo yi aso ala won.
Sugbon gbogbo wa ni amo pe ile to toro, omo ale iba ni ko ti dagba.
E je ki afi olori ede eletididi ati awon aja re sile ki won ma gbo, sebi offisi lo nkehin aakowe, ko de si bi omode se tete ji de oko to, oko lo ma ba kukute.
Eni ti o fe dagba, ko kin ri agba fin. Bi omode de ni aso bi agba, ko le ni akisa bbi agba.
Alakisa to njo loru ni oro won, bope,boya, ile a mo.
Kobo mewa mi nu.

No comments:

Post a Comment

NEW HOME, CAR OWNERS EMERGE AS COWLSO ENDS THREE DAY WOMEN'S CONFERENCE.

As the 23rd edition of the National Women's Conference organized by the Committee of Wives of Lagos State Officials (COWLSO), ends today...